JS3 Yoruba Mock Past Questions-Third Term
ÌDÁNWÒ SÁÀ KEJÌ FÚN SÉ̩KÓ̩NDÌRÌ KÉKERÉ ÌPÍLE KE̩TA ODÚN
ÀKÀYÉ ÌPÍN KÌN ÍN NÍ
Ka àwo̩n àyo̩kà ìsalè̩ yìí, kí o sì dáhùn àwo̩n ìbéèrè tí ó tè̩lé wo̩n.
Tádé , Tó̩lá, Búkì, àti S̩o̩lá jé. Ò̩ré̩ tímó̩ tímó̩, s̩ùgbó̩n Tádé àti Tó̩lá ti jé̩ ò̩ré̩ láti ìgbà tí wó̩n ti wà ní ilé ìwé alákò̩ó̩bè̩rè̩ kí wó̩n tó pàdé Búkì àti S̩o̩lá ní ilé ìwé girama. Àwo̩n ò̩ré. Wò̩nyí jo̩ máa n s̩e às̩epò̩, bíi as̩o̩ rírà, óúnje̩ àje̩pò̩, ìwé kíkà papò̩, bàtà rírà àti irun dídì. Bákan náà ni gbogbo nnkan wo̩n máa n rí, báyìí ni àwo̩n ò̩ré̩ wò̩nyìí s̩e tí wó̩n fi jade ilé-ìwe girama tí wó̩n sì dé ilé-ìwé gíga.
Ní ilé ìwé gíga yìí ni w̩ó̩n ti pàdé Tolú àti Dàpò̩ tí wó̩n jé̩ ò̩ré̩, inú àwo̩n ò̩ré̩ méjì yìí kò dùn sí àwo̩n ò̩ré̩ mérin wò̩nyí nítorí bí wo̩n s̩e n ran ara wo̩n ló̩wó̩ lé̩nu è̩kó̩, nínú ìdánwò àti ìrànló̩wó̩ owó, wó̩n sì n wá ò̩nà láti da àárín wo̩n rú.
Ní o̩jó̩ kan, àwo̩n ò̩ré̩ méjì yìí lo̩ bá Tádé, wó̩n ní Tó̩lá so̩ wí pé òun ni Tádé máa n jí wò nínú ìdánwò bákan náà ni wó̩n tún ló̩ ba Tó̩lá, wó̩n ní Tádé so̩ wí pé nípasè̩ ìrànló̩wó̩ owó òun ni Tó̩lá fi n lo̩̩ sí ilé-ìwé, Nítorí àwo̩n òbí rè̩ jé̩ tálákà. Ò̩rò̩ yìí dá ìjà sílè̩ láààrín Tádé àti To̩lá tóbé̩è̩ tí ìjà náà ran Búkì àti S̩o̩lá nítorí wí pé Tádé ní Búkì n gbè lé̩̩hìn Tó̩lá tí Tó̩lá náà sì ní è̩hìn Tádé ni S̩ó̩lá wà.
Read Also:
Orí ìjà yìí ni àwo̩n ò̩ré̩ wò̩nyí wà tíwó̩n fi s̩e ìdánwò às̩ejáde èyí tí ó s̩e àkóbá fún wo̩n nínú è̩sìn ìdánwò às̩ejáde wo̩n.
Dáhùn àwo̩n ìbéèrè wò̩nyí
- Àjo̩s̩epò̩ àwo̩n ò̩ré̩ mé̩rin inú àkàyé òkè yìí jé̩——fún Tolú àti Dàpò̩. (a) àpó̩nlé (b) ìbànújé̩ (c) ìdùnnú (d) ìfé̩ (e) ìwúrí
- Èwo nínú àwo̩n nnkan wò̩nyí ni àwo̩n ò̩ré̩ mé̩rin wò̩nyí kìí s̩e papò̩? (a) as̩o̩ rírà papò̩ (b) irun irú kan náà (c) ìwé kíkà papò̩ (d) o̩ko̩ fífé̩ papò̩ (e)óunje̩ jíje̩ papò̩
- Àwo̩n won i ò̩ré̩ méjì àkó̩kó̩? (a) Búkì àti S̩o̩lá (b) Dàpò̩ àti Tolú (c) S̩o̩lá àti Dàpò̩ (d) Tádé àti Tó̩lá (e) Tó̩lá àti Búkì.
- Ta ni kò sí lára àwo̩n ò̩ré̩ mé̩rin inú àkàyé yìí? (a) Búkì (b) Dàpò̩ (c) S̩ó̩lá (d) Tádé (e) Tó̩lá
- Kín ni ó se àkóbá fún èsì ìdánwò às̩ejáde àwo̩n ò̩ré̩ mé̩rin wò̩nyí? (a) àìkàwé wo̩n (b) àkóbá olùkó̩ wo̩n (c) àìsanwó parí is̩è̩ (d) ìdánwò wo̩n le (e) ìjà tí ó wà láàrín wo̩n.
ÀKÀYÉ KEJÌ
Ò̩gè̩dè̩ jé̩ ò̩kan lára àwo̩n ohun ò̩gbìn ilè̩ wa. Àwo̩n àgbè̩ tó wà ní ilè̩ igbó ló máa n gbin ò̩gè̩dè̩. Omi s̩e pàtàkì fún dídàgbà ò̩gè̩dè̩. A ní orísìí ò̩gè̩dè̩ méjì. Èkínní ni èyí tí à n pè ní ò̩gè̩dè̩ àgbàgbà. Irú ò̩gè̩dè̩ yìí máa n tóbi daadaa. Orísìí kejì ni ò̩gè̩dè we̩e̩re̩. èyí lè jé̩ párántà tàbí ò̩mìnì. Igi tó n so ò̩gè̩dè̩ yálà párántà tàbí àgbagbà kò dàbí orís̩ìí igi yòókù. Ó ro̩rùn láti fi àdá gé nítorí pé igi rè̩ rò̩.
Nígbà tí ò̩gè̩dè̩ bá dàgbà tí èso rè̩ sì ti gbó, á máa s̩á a. ò̩gè̩dè̩ mìíràn á ti so̩ ní ìdí èyí tí a sá o̩mo̩ lórí rè̩, a ó wá gé igi rè̩ lulè̩. Ìdí nìyí tí a fi n pòwe pé,”bí iná bá kú á feérú bojú, bí ò̩gè̩dè̩ kú a fo̩mo̩ rè̩ ró̩pò. Igi ò̩gè̩dè̩ tí ó so̩ ní ìdí rè̩ yìí ni yóò dípò èyí tí a gé lulè̩. Ìgbà èè̩rùn ni ò̩gè̩dè̩ máa n pò̩ lójà. Ò̩gè̩dè̩ we̩e̩re̩ ni a fí máa n panu tí ó bá ti pó̩n.
Ìwúlò ò̩gè̩dè̩ àgbagbà pò̩ púpò̩. A lè fi dúdú rè̩ s̩e èlùbó̩, a lè sè é mó̩ is̩u láti gún iyán jé̩, a tún lè fi s̩e às̩áró tàbí kí á fi dín ìpékeré. Bí ò̩gè̩dè̩ àgbagbà bá pó̩n, a lè jé̩ é̩ ní tutu tàbí kí a sè é jé̩. Tí a bá fé̩, a lè sè é mó̩ è̩wà tàbí kí a dín in ní dodo. Àwo̩n mìíràn a sì máa fi pó̩n o̩tí àgàdàngídí.
Dáhùn àwo̩n ìbéèrè wò̩nyí
- Èwo ni kìí s̩e òótó̩ nípa ò̩gè̩dè̩ nínú àwo̩n gbólóhùn wò̩nyìí? (a) a lè fi ò̩gè̩dè̩ àgbàgbà pípo̩n po̩n o̩tí (b) Èso ni ò̩gè̩dè̩ párántà (c) ìgbà òjò ni ò̩gè̩dè̩ máa n pò̩ ní o̩jà (d) ilè̩ igbó ni ó dára jù fún ò̩gè̩dè̩ (e) orísi ò̩gè̩dè̩ méjì ni ó wà.
- Ò̩gè̩dè̩ ni a fí n se àwo̩n óunjé̩ wò̩nyìí àyàfi (a) ègbo (b) èlùbó̩ (c) dodo (d)ìpékeré (e) iyán.
- A lè lo ò̩gè̩dè̩ dúdú fún ò̩kan nínú àwo̩n óúnje̩ wò̩nyìí? (a) àádùn (b) às̩áró (c) ègbo (d) ìkó̩ko̩ré̩ (e) láfún
- kín ni igi ò̩gè̩dè̩ fi yàtò̩ sí àwo̩n igi yòókù?igi ò̩gè̩dè̩ máa n (a) fè̩ (b) ga (c) le (d) rò̩ (e)wó̩wé
- Ìgbà——–ni ò̩gè̩dè̩ máa n pò̩ ní o̩jà. (a) è̩è̩rùn (b)òjò (c) òtútù (d) ò̩gìnnìtin (e) o̩yé̩.
- “Agbo ilé wa” je̩ mó̩ àròko̩ (a) alálayé (b) alárìíyànjiyàn (c) as̩àpèjúwe (d) asò̩tàn (e)oníròyìn.
- Orí ò̩rò̩ won i ó je̩ mó̩ àròko̩ alápèjúwe nínú ìwò̩nyí? (a) Bí mo s̩e ìsinmi kérésìmesì tó io̩ (b) is̩é̩ àgbè̩ dára ju is̩é̩ gbé̩nagbé̩nà (c) omi òjò (d) óúnje̩ tí mo fé̩ràn jùlo̩ (e) ò̩ré̩ mi tímó̩tímó̩.
- Irú àròko̩ won i “aye̩ye̩ ìso̩mo̩lórúko̩ àbúrò mi” je̩ mó̩? (a) alálàye (b) alárìíyanjiyàn (c) as̩àpèjúwe (d) onílétà (e) oníròyìn.
- ” ìyá mi ò̩wó̩n” le je̩yo̩ nínú àròko̩ (a) alálàyé (b) asò̩tàn (c) lé̩tà àìgbè̩fé̩ (d) lé̩tà gbè̩fé̩ (e) oníròyìn.
- Èwo ni àko̩lé rè̩ je̩ mó̩ àròko̩ alárì’iyànjiyàn? (a) as̩o̩ e̩bí (b) is̩é̩ tí ó wù mí s̩e ló̩jó̩ iwájú (c) o̩jà o̩ba ilú mi (d) o̩jó̩ burúkú, èsù gbomi mu (e) o̩mo̩kùnrin wúlò ju o̩mo̩bìnrin lo̩.
- kó̩nsónántì àìkùnyùn afeyínfètèpè afúnnupè ni (a) b (b) d (c) f (d) g (e) i
- Nípasè ní ò̩rò̩ àyálò síléètì fi wo̩ inú èdè Yorùbá. (a) è̩sìn (b) ètò è̩kó̩ (c) ètò ìdájó̩ (d) ohun amúlùdùn (e) o̩rò̩ ajé.
- Èwo ni fáwélì àyanupè nínú àwo̩n wò̩nyí? (a) A (b) E (c) I (d) O (e) U.
- Èwo ni fáwé̩lì àárín nínú àwo̩n wò̩nyí? (a) E (b) I (c) O (d) U (e) A.
- Èwo ni a kò lè fi ojú rí nínú àwo.n è̩yà ara ìfò̩ wò̩nyí? (a) àfàsé (b) àjà e̩nu (c) èrìgì (d) èdò̩fóró (e) òlélé
- kìn ni ìró akùnyùn túmò̩ sí? Ìró tí n darí (a) àfàsé (b) è̩dò̩fóró (c) ìfun (d) imú (e) tán-án-ná.
- kó̩nsónántì aránmúpè asesílébù ni (a) b (b) d (c) f (d) I (e) n.
- Kónsónántì mélòó ni ó wà nínú álífábé̩è̩tì Yorùbá? (a) méje (b) mé̩jo̩ (c) méjìlá (d) méjìdínlógún (e) márùndínló̩gbò̩n.
- Ìró kín ní à n pè nígbà tí àfàsé bá dí ihò imú tí èémí sì gba ò̩nà e̩nu jade? (a) àdinupè (b) àìkùnyùn (c) àkùnyùn (d) àìránmúpè (e) àránmúpè.
- ètè rí roboto nígbà tí a pe ìró (a) a (b) an (c) I (d) in (e) u.
- Èwo nínú àwo̩n wò̩nyí ni èémí tí a fí n gbé ìró ìfò̩ jade ti n wá? (a) àfàsé (b) È̩dò̩fóró (c) gògòngò (d) ìfun (e) tán-án-ná.
- Ìpín Alántakun sí sílébù ni (a) Alá-n-takùn (b) A-lan-takùn (c) A-la-ntakun (d) A-la-n-takun (e)A-la-n-ta-kun.
- orís̩ìí `amì ohùn mélòó ni ó wà nínú èdè Yorùbá? (a) ò.kan (b) méjì (c) mé̩tà (d) mé̩rin (e) mé̩fà.
- .K’onsón’antì afèji-ètè-pè ni (a) B ((b) D (c) F (d) G (e) H
- Gbogbo àwo̩n è̩yà ara ìfò̩ wò̩nyí ni a lè rí níbi àfipè àkànmó̩lè̩ àyàfi (a) àfàsé (b) àjà e̩nu (c) ahó̩n (d) èrìgì (e) ìgànná ò̩fun.
- lé̩hìn ìgbà tí ìsúnkì bá wáyé “o̩mo̩-kí-o̩mo̩” yóò pada di (a) o̩mo̩-kó̩mo̩ (b) o̩mo̩kó̩-mo̩ (c) o̩mo̩kó̩mo̩ (d) o̩-mo̩ko̩mo̩ (e) o̩mo̩ kú o̩mo̩
- Inú ò̩wó̩ álífábé̩è̩tì won i a tí rí èyí tí a kò lè fi àmì ohùn sí lórí nínú àwo̩n wò̩nyí ò̩wó̩ (a) a.b.n. (b) a.i.e (c) e.o.u (d) i.o.m (e) u.i.n
- Èwo ni à n lò fún ìró èdè pipe nínú è̩yà ara wò̩nyí? (a) apá (b) ètè (c) etí (d) ojú (e) orí.
- Orísìí ìró ohùn mélòó ló wà nínú èdè Yorùbá? (a)ò̩kan (b) méjì (c) mé̩ta (d) mé̩rin (e) márùn-ún
- Èwo ni kó̩nsónántì afèrìgìpé nínú àwo̩n wò̩nyí? (a) B (b) D (c) F (d) G (e) H.
- Àpe̩e̩re̩ ò̩rò̩ aró̩pò àfarajórúko̩ ni ìwó̩nyìí àyàfi (a) àti (b) àwo̩n (c) èmi (d) è̩yin (e) òun.
- “As̩o̩ pupa ni Délé wò̩” pupa jé̩ ò̩rò̩ (a) àpèjúwe (b) arópò orúko̩ (c) ató̩kùn (d) ìs̩e (e) orúko̩.
- Èwo ni kìí s̩e ò̩rò̩ aró̩pò àfarajórúko̩ nínú àwo̩n wò̩nyí? (a) àwo̩n (b) èmi (c) è̩yin (d) Ìwo̩ (e) Ó.
- Àpe̩e̩re̩ gbólóhùn oníbò̩ ni (a) Adé pa e̩ja odò lánàá (b) Bádé àti ò̩ré̩ rè n je̩ àkàrà (c) eré ìdárayá dára (d) Mó kilo fún Báyò̩ kí ó s̩óra rè̩ (e) ojú ajá n s̩è̩jè̩.
- .” Ayò̩ n lo̩ sí odò” ò̩rò̩ ató̩kùn wo n i ó wà nínú gbólóhùn yìí? (a) ayò̩ (b) n (c) lo̩ (d) sí (e) odò.
- Ò̩rò̩ orúko̩ tó bá s̩áájú nínú gbólóhùn máa n s̩is̩é̩ (a) àbò̩ (b) àpó̩nlé (c) è̩yàn (d) ìrànwó̩ ìse (e) olùwà.
- Ìyá náà ra è̩wà sè tà” ò̩rò̩ ìs̩e mélòó ni ó wà nínú gbólóhùn yìí? (a) ò̩kan (b) méjì (c) mé̩ta (d) mé̩rin (e) márùn-ún.
- Kóláwo̩lé pa e̩ran ò̩yà ní oko’ ò̩rò̩ ìs̩e inú gbólóhùn yìí ni (a) e̩ran (b) kóláwo̩lé (c) ni (d) ò̩yà (e) pa.
- Èwo nínú àwo̩n ò̩rò̩ wò̩nyí ni kìí s̩e ò̩rò̩ àsopò̩? (a) àbò̩ (b) àmó̩ (c) àti (d) s̩ùgbó̩n (e) yálà.
- Ò̩rò̩-àró̩pò orúko̩ ni (a) àwo̩n (b)èmi (c) è̩yin (d) ìwo̩ (e) o .
- Báyò̩ lo̩ sí Ìbàdàn “Ìbàdàn” jé̩ ò̩rò̩ (a) àpèjúwe (b) àsopò̩ (c) ató̩kùn (d) ìs̩e (e) orúko̩.
- Olú je̩ iyán yó bámúbámú. Ìsò.rí ò̩rò̩ won i a fa ìlà sí? Ò̩rò̩ (a) àpó̩nlé (b) àsopò̩ (c) ató̩kùn (d) ìse (e) orúko̩.
- Olú mu o̩tí yó bámúbámú. Ò̩rò̩ ìs̩e mélòó ló wà nínú gbólóhùn yìí? (a) ò̩kan (b) méjì (c) mé̩ta (d) mé̩rin (e) márùn-ún.
- “Wó̩n ra bàtà ní ò̩jà” Wó̩n jé̩ ò̩rò̩ (a)àfarajórúko̩ (b)àpèjúwe (c) àpó̩nlé (d) aró̩pò orúko̩ (e) ìs̩e.
- ‘ Bádé pè̩lú Ye̩mí ni wó̩n jo̩ lo̩ sí oko. Ò̩rò̩ àsopò̩ inú gbólóhùn yìí ni (a) Bádé (b) Bádé àti Ye̩mí (c) lo̩ sí (d) pè̩lú (e) oko.
- ‘ Táyé àti Ké̩hìndé wo̩ orís̩ìí as̩o̩ kan náà. Ò̩rò̩ àsopò̩ inú gbólóhùn òkè yìí ni (a) àti (b) kan (c) Ké̩hìndé (d) orís̩ìí (e) wo̩.
- A je̩ e̩ran ògúnfe lánàá. Á jé̩ ò̩rò̩ (a) àpónlé (b) aró̩pò orúko̩ (c) àsopò̩ (d) ató̩kùn (e) orúko̩.
- “ Bádé lo̩ ra o̩s̩e̩ tí yóò lò. Ò̩rò̩ orúko̩ ní ipò àbò̩ nínú gbólóhùn òkè yìí ni (a) Bádé (b) o̩s̩e̩ (c) rà (d) tí (e) yóò.
- Àlàbí sùn fo̩nfo̩n. fo̩nfo̩n jé̩ ò̩rò̩ (a) àpèjúwe (b) àpó̩nlé (c) atókùn (d) ìs̩e (e) orúko̩
- ’ Mojísó̩lá ló̩ ra as̩o̩ ní Èkó. Ìsò̩rí ò̩rò̩ won i a fa ìlà sí nídìí? Ò̩rò̩ (a) aró̩pò orúko̩ (b) àsopò̩ (c) ató̩kùn (d) ìs̩e (e) orúko̩.
- Èwo nínú àwo̩n ò̩rò̩ wò̩nyí ló bá liana àko̩tó̩ Yorùbá òde-òní mu? (a) níg bà tí (b) nígb àti (c)nígbàtí (d) nígbà tí (e) ní gbàtí.
- Nínú àko̩tó̩ Yorùbá òde òní “Òshogbo” yóò yí padà di (a) òssogbo (b) òshogboo (c) òsh ogbo (d) ò sogbo (e) Òs̩ogbo.
- Tó̩ka sí ò̩rò̩ tí kò bá àko̩tó̩ Yorùbá mu (a) ayé (b) aiya (c) e̩ye̩lé (d) kín ni (e) òs̩ogbo.
- Báwo ni a s̩é n ko̩’ò̩ffà’ ní liana akó̩tó̩ Yorùbá òde òní? (a) ò̩ ffa (b) ò̩fàà (c) ò̩ff à (d) ò̩ fa (e) ò̩fà.
- Tó̩ka sí gbólóhùn tí a ko̩ ní ìlànà àko̩tó̩ òde òní nínú ìwò̩nyí (a) mo n lo̩ (b) món lo̩o̩ (c) mo nlo̩ (d) mo on lo̩ (e) mo n lo̩o̩.
- Kín ni ó fàá tí Òdùduwà fi kúrò ní ìlú Mé̩kà? (a) Àjàkálè̩ àrùn ló l’e wo̩n wá sí Ifè̩ (b) ìjà è̩sìn tí ó bé̩ sílè̩ ní ìlú Mé̩kà (c) ìyàn nlá tí ó mú (d) kíkó tí wó̩n kó wo̩n lé̩rú (e) kíkú tí àwo̩n ò̩dó̩ n kú.
- Orúko̩ asáájú tí Odùduwà bá ní Ilé-ifè̩ ni (a) Àgbo̩nnìrègún (b) agbo̩mo̩lá (c) aláàfin (d) onísabé̩ (e) s̩ò̩ún .
- Ta ni ó wà ní ipò ke̩rin nínú àwo̩n o̩mo̩ Ò̩kànbí? (a) alákétu (b) olówu (c) ò̩ràngún (d) ò̩rànmíyàn (e) o̩ba ìbíní.
- Kín ni ìpín o̩ba onísábe̩ nínú ogún odùduwà? (a) adé (b) E̩ran ò̩sìn (c) ilé (d) ìlè̩kè̩ (e) owó e̩yo̩.
- Báwo ni ò̩rànmíyàn s̩e di e̩ni tó ló̩rò̩ ju àwo̩n è̩gbó̩n rè̩ yókù? Nípa (a) àjo̩ dídá (b) is̩é̩ ìs̩ègùn (c) ìs̩ákó̩lè̩ gbígbà (d) òwò s̩ís̩e (e) o̩jà títà.
- Gbogbo àwo̩n wò̩nyí ni wó̩n kópa nínú bí èdè yorúbà s̩e di kíko̩ sílè̩ àyàfi (a) Gollmer C.A (b) Hannah aya kilham (c) John c. raban (d) O̩báfé̩mi Awólówò̩ (e) Wood J.B.
- Ìjo̩ won i ó se agbáte̩rù kíko̩ èdè Yorùbá sílè̩? Ìjo̩ (a) elétò (b) kátólííkì (c) kérúbù (d) onítè̩bo̩mi (e) síé̩me̩e̩sì.
- Kín ni orúko̩ tí àwo̩n òyìnbó kó̩kó̩ pe àwo̩n Yorùbá ní ilè̩ sàró? (a) akú (b) èké (c) e̩kú (d) ikú (e) òkú.
- Ta ni ó kókó̩ fi èdè Yorùbá s̩e ìwáásù ní ilè̩ Sàró? (a) fágúnwà D.O (b) Hannah aya kilham (c) o̩látúnjí ò̩pádò̩tun (d) Samuel Ajàyí Crowther (e) wood J.B.
- kí ló fàá tí àwo̩n ajíhìnrere è̩sìn kírísítì ilè̩ Yorùbá s̩e fi Àjàyí Crowther sí ipò asáájú nínú kíko̩ èdè Yorùbá sílè̩? Nítorí ó (a) fé̩ràn àwo̩n o̩mo̩lé̩hìn kírísítì (b) jé̩ ìran Yorùbá (c) jé̩ oníwàásù nínú ìjo̩ (d) ní e̩nu dídùn nínú ò̩rò̩ síso̩ nípàdé (e) n túmò̩ bíbélì sí Yorùbá.
- Èwo nínú àwo̩n oúnje̩ wò̩nyí ló gbajúmò̩ láàrín àwo̩n Ìjè̩bú? (a) Ègbo (b) È̩wà (c) Ìkó̩ko̩ré̩ (d) iyán (e) láfún.
- Báwo ni a s̩e n pe àpèje̩ o̩ba È̩gbá (a) Aláké (b) Àtào̩jà (c) ògìyán (d) olówu (e) O̩wá.
- Èwo nínú àwo̩n wò̩nyí ni ó súnmó̩ Yorùbá àjùmò̩lò jùlo̩? (a) È̩gbá (b) Èkìtì (c) ìjè̩bú (d) Ondó (e) ò̩yó̩.
- Ta ni ó te̩ ìlú Ò̩Yó̩ dó? (a) O̩bàtálá (b) Odùduwá (c) Ò̩kànbí (d) Olówú (e) Ò̩rànmíyàn.
- È̩yà Yorùbá won i ó n pe’Àkàrà’ ní ÀKàà? (a) È̩gbá (b) Ìjè̩bú (c) Ìjè̩sà (d) Ondó (e) Ò̩yó̩.
- Àwo̩n wo ló ni dadakúàdà? (a) È̩gbá (b) È̩gbádò (c) ìgbómínà (d) Ìje̩sà (e) ò̩yó̩.
- Èwo nínú ewì alohùn yìí ni a kì’I lò ní ibi ìkómo̩jáde? (a) Alámò̩ (b) Bò̩lò̩jò̩ (c) Ìrèmò̩jé̩ (d) Obitun (e) Rárà.
- È̩yà Yorùbá wo ló ni è̩fè̩? (a) Èkìtì (b) È̩gbádò (c) Ìjè̩bú (d) Ìjè̩s̩à (e) Ò̩yó̩.
- Àwo̩n e̩lé̩sìn ìbílè̩ wo l’o ni ijó bàtá? (a) olórò (b) o̩ló̩ya (c) onídán (d) onífá (e) onís̩àngó.
- Is̩é̩ won i a s’abà máa n fi ìlù gbè̩du jé̩ láwùjo̩ Yorùbá? (a) ìjúbà àgbà (b) ìkìlò̩ (c) ìsígun (d) ìtúfò̩ o̩ba (e) ìwúre.
- Gbogbo àwo̩n wònyìí ni ó jé̩ mó̩ ewì alohùn aje̩máye̩ye̩ àyàfi (a) bò̩lò̩jó̩ (b) e̩kún ìyàwó (c) ìyè̩rè̩ ifá (d) orin etíye̩rí (e) rárà
- Ewì tí ó wó̩pò̩ láàárín àwo̩n È̩gbá ni (a) alámò̩ (b) ape̩pe̩ (c) àsamò̩ (d) ègè (e) obitun.
- È̩yà Yorùbá won i ó n sá alámò̩? (a) è̩gbá (b) Èkìtì (c) ìkàlé̩ (d) Ìjè̩sà (e) Ondó
- Báwo ni a s̩e n pe àpèje̩ o̩ba ìlú Ò̩ndó? (a) Aláàfin (b) Èwí (c) o̩wá (d) òs̩emàwé (e) Òò̩ni.
- Ìlù tí àwo̩n babaláwo n lù ló̩jó̩ o̩dún ifá ni a n pè ní (a) àgè̩rè̩ (b) bàtá (c) dùndún (d) gbè̩du (e) ìpèsè.
- Òrìs̩à won i àwo̩n Yorùbá m’aa n bo̩ láti fi s̩e ìrántí àwo̩n baba nlá wo̩n tí ó ti kú? (a) Egúngún (b) Èsù (c) Ògún (d) S̩àngó (e) S̩ànpò̩nná.
- Àwo̩n òsìsé̩ won i a n kí báyìí? ‘Ojú gbòòrò o (a) Alágbè̩de̩ (b) Al’aró (c) Akò̩pe̩ (d) Ape̩ja (e) onídìrí.
- Òrìsà àwo̩n Yorùbá won i ó kórira àdí? (a) Ès̩ù (b) O̩bàtálá (c) Ògún (d) O̩ya (e) S̩ànpò̩nná.
- Èwo nínú àwo̩n ewì alohùn wò̩nyìí ni ó wó̩pò̩ ní agbègbè Ondó? (a) Alámò̩ (b) ape̩pe̩ (c) E̩kún ìyàwó (d) Ègè (e) orin obitun.
- Àwo̩n won i àwo̩n Yorùbá n kí ni Àre̩pó̩n àre̩dú o ? (a) adé̩mu (b) alágbè̩de̩ (c) aláró (d) awakò̩ (e) onídìrí.
- Èwo ni oríkì àbíso̩ fún o̩mo̩kùnrin nínú àwo̩n wò̩nyí? (a) Àbíké̩ (b) Àjo̩ké̩ (c) Àkànbí (d) Àlàké (e) Às̩àké̩.
- Gbogbo àwo̩n orúko̩ wò̩nyí jé̩ ti àbíkú ní ilè̩ Yorùbá àyàfi (a) Bámitalé̩ (b) dúrójayé (c)èkísàátán (d) Kòsó̩kó̩ (e) Olóròdé.
- Èwo ni a fi n bo̩ ògún nínú àwo̩n wò̩nyí? (a) Adìye̩ (b) àgbò (c)àgùntàn (d) Ajá (e) Ewúré̩.
- Ìdílé won i ó n jé̩ Ò̩jé̩dìran? (a) Eléégún (b) Olóyè (c) onílù (d) onífá (e) onís̩àngó.
- Èwo ni wo̩n kìí fi s̩e àdúrà fún o̩mo̩ ìkókó ní ibi ìso̩mo̩lórúko̩? (a) Obì (b) Orógbó (c) Òbúko̩ (d) O̩tí (e) Owó.
- Ta ni O̩l̀́́álék̀è pè láti bá a ko̩ ̀iran ̀às̩írí ìd́ánwò tí ó rí sílè̩? (a) àlùfáà (b) jídé (c) jùmò̩ké̩ (d) ò̩mò̩wé (e) tó̩lá.
- Kíláàsì kelòó ni O̩l̀́́álék̀è wà tí ó fi rí ìbéèrè ìdánwò àwo̩n oníwèé mé̩wàá? Kílààsì (a) kejì (b) ke̩fà (c) ke̩rin (d) ke̩ta (e) kìn-ín-ní.
- Ta ni O̩l̀́́álék̀è ní ó jé̩ dandan fún láti kúrò ní ìlú laì sùn mó̩jú? (a) baba awo (b) bàbá Tó̩lá (c) Fadéké̩ (d) Jùmò̩ké̩ (e) Olúwo̩lé.
- Èló ni Ò̩gbé̩ni Òjó dà sílè̩ láti fi kún owó bàbá olóògùn tí oògùn rè̩ bá s̩is̩é̩? Pó̩ùn (a) márùn-ún (b) méjì (c) mé̩fà (d) mé̩rin (e) mé̩ta.
- Àwo̩n is̩é̩ àsírí ìdánwò tí O̩l̀́́álék̀è rí lójú àlá ní s̩ís̩è̩-n-tè̩lé jé̩ (a) márùn-ún (b) méjì (c) mé̩fà (d) mé̩rin (e) mé̩ta.
- Aye̩ye̩ ti e̩léèkelòó ni kábíyèsí ìlú Fèyíkó̩gbó̩n so̩ pé ó ń bò̩ ló̩nà? (a) e̩lé̀èkeje (b) e̩lé̀èke̩fà (c) e̩lé̀èke̩jo̩ (d) e̩lé̀èke̩sàn-án (e) e̩lé̀èke̩wàá.
- Lára àǹfààní aye̩ye̩ Fèyíkó̩gbó̩n nìwo̩nyí àyàfi pé ó ń mú (a) ìdàgbàsókè bá ìlú (b) kí àwo̩n o̩mo̩ ìlú mo̩ rírì è̩kó̩ (c) kí ìfé wà láàrín ìlú (d) kí oúnje rojú śii nínú ìlú (e) ò̩làjú bá ìlú.
- Ta ni Fikáyò̩mi nínú ìwé Olú O̩mo̩? O̩mo̩ oleo (a) àgùro (b) ajiroba (c) jagun (d) iyalode (e) otun.
- Kin ni olóyè jagun so̩ pé yóò s̩e̩le̩ si o̩do̩mo̩kùnrin tabi o̩do̩mo̩b̀inrin t́I ́o ko̩ o̩ro̩ ìfé̩ lé àyà ní ijinji ayé rè̩? Ko ni (a) dé ipo pataki (b) ja fafa (c) lenu oro lawujo egbe (d) mo iwe re (e) lowo lo̩wo̩ leyinwa o̩la.
- Ta ni o ́mu aba pipe alagbaaa ati awon eegun yooku si ayeye Fèyíkó̩gbó̩n wá? (a) àgùro (b) ajiroba (c) jagun (d) iyalode (e) otun.
- Ta ni o yan is̩e̩ olùkó̩ láayò ninú awo̩n wo̩nyí (a) afolabi (b) ajamu (c) amosa (d) ayofe (e) oluseyi.
- Èwo ninu awon ire oko yii ni wo̩n sa si oris̩a ni ile Ayo̩delé? (a) agbado (b) eree (c) koko (d) orogbo (e) ro̩ba.
- Orule mokanlelogun ni ́o wan i (a) aru e̩gan (b) igbagbo̩ (c) jagun ibagbe (d) orita basorun (e) olo̩rundá abaa.
- Elo ni Ayo̩délé ń gba ló̩wó̩ awo̩n ayalégbé fún ojúlé ko̩o̩kan?——– naira. (a) apo kan (b) e̩e̩de̩gbe̩ta (c) e̩gbe̩rin (d) e̩gbe̩run kan (e)irinwo.
- O̩kan ĺara ̀awo̩n nnkan t́I ̀ayo̩déĺe gbiǹ śI oko re̩ ni (a) agbado (b) e̩ge̩ (c) kasu (d) ob̀I (e) o̩ka baba.
- E̩ni tí ó tú às̩írí o̩jà tí Fúnké̩ gbé fun àwo̩n as̩ó̩bodè ni ——rè̩.(a) àbúrò (b) bàbá (d) o̩ló̩pàá (e) ò̩ré̩.
- Kílógíráàmù kokéènì tí Fúnké fé̩ gbé ní orílè̩-èdè Libya tó bu ú lówó̩ jé̩ (a) aárùndínló̩gó̩rùn-ún (b)èjìléló̩gó̩rin (d)è̩rìndínló̩gó̩rùn-ún (e) è̩tàléló̩gó̩rin.
- Ní àkókò tí Funke n sùn ní ojú o̩nà aghadez ni —-so̩ o̩ ní e̩sè̩̀. (a) ej̀o (b) e̩gún (c) ìbo̩n (d) igi (e) ìgò.
- Ibo ni Funke toju oogun oloro ti o gbe lo Libya si? Inu (a) bata (b) buredi (c) ibo̩se̩ (d) ikun (e) irun.
- Ò̩pò̩ló̩ ni àìrira e̩ni k̀o je̩ ki——ḱo tan ninu ewi “ À̀iŕira e̩ni”. (a) aso̩ (b) ìjà (c) òsì (d) o̩ràn (e) o̩tè̩.
- Ààre̩-ò̩nà-kakànfò̩ jé̩ olóyè (a) ogun (b) è̩sìn (c)òs̩èlú (d)awo.
- “ ìpèsè” jé̩ ìlù fún àwo̩n (a) olùsìn ògún (b)onís̩àngó (c) babaláwo (d)o̩ló̩sànyìn-ìn.
- ——ni a kì ni” aló̩májàá o̩kùnrin násán násán, ó yí awo̩ inú pò̩ mó̩ tè̩yìn títíké tíké̩”(a) ebi (b)ìbínú (c)igbe (d)ìgbónára.
- O̩ba àkó̩kó̩ ní Ò̩yó̩ ni (a) odùduwà (b)aólè̩ (c) ò̩rànmíyàn (d) lámúrúdu.
- Èwo ni a máa lé só jú (a)osùn (b)làálì (c)tìròó (d)àtíkè.